YOR Proverbs Chương 8

Proverbs 8

YOR · So sánh · Âm thanh

1Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta? 2Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà, 3ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú, 4“Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè; 5Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ kọ́gbọ́n; 6Ẹ gbọ́, nítorí tí èmi ó sọ̀rọ̀ ohun iyebíye; 7ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́, 8Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi ni ó tọ́, 9Fún olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà; 10Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà, 11nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù iyùn lọ, 12“Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye; 13Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìkórìíra ibi 14Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmi 15Nípasẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkóso 16Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ-aládé ń ṣàkóso, 17Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi, 18Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà, 19Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ; 20Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo, 21mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mi 22“Èmi ni Olúwa kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀. 23a ti yàn mí láti ayérayé, 24Nígbà tí kò tí ì sí Òkun, ni a ti bí mi, 25kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn, 26kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀ 27Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn, 28nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfúrufú lókè 29nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi Òkun 30Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ 31Mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dá 32“Nítorí náà báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi, 33Fetí sí ìtọ́sọ́nà mi kí o sì gbọ́n; 34Ìbùkún ni fún ẹni tí ó fetísílẹ̀ sí mi, 35Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi rí ìyè Olúwa. 36Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti rí ń pa ara rẹ̀ lára

Đã đạt giới hạn hàng ngày

Nâng cấp gói của bạn để tiếp tục sử dụng các tính năng AI với giới hạn hàng ngày cao hơn.

So sánh tất cả các gói →