Приче 15
1Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú padà 2Ahọ́n ọlọ́gbọ́n a máa gbé ìmọ̀ jáde 3Ojú Olúwa wà níbi gbogbo, 4Ahọ́n tí ń mú ìtura wá jẹ́ igi ìyè 5Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀ 6Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra, 7Ètè olódodo ń tan ìmọ̀ kalẹ̀; 8Olúwa kórìíra ìrúbọ àwọn ènìyàn búburú 9Olúwa kórìíra ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú, 10Ẹni tí ó kúrò lójú ọ̀nà yóò rí ìbáwí gan an, 11Ikú àti ìparun ṣí sílẹ̀ níwájú Olúwa, 12Ẹlẹ́gàn kò fẹ́ ẹni tí ń ba wí: 13Inú dídùn máa ń mú kí ojú túká 14Ọkàn olóye ń wá ìmọ̀ 15Gbogbo ọjọ́ àwọn olùpọ́njú jẹ́ ibi, 16Ó sàn kí ó má pọ̀, kí ìbẹ̀rù Olúwa sì wà 17Oúnjẹ ewébẹ̀ níbi tí ìfẹ́ wà 18Ènìyàn onínú ríru dá ìjà sílẹ̀ 19Ọ̀nà ọ̀lẹ ni ẹ̀gún dí, 20Ọlọ́gbọ́n ọmọ mú inú baba rẹ̀ dùn, 21Inú ènìyàn aláìlóye a máa dùn sí ìwà òmùgọ̀; 22Ìgbèrò a máa dasán níbi tí kò sí ìmọ̀ràn; 23Inú ènìyàn a máa dùn nígbà tí ó bá fèsì tó yẹ 24Ọ̀nà ìyè ń lọ sókè fún ọlọ́gbọ́n 25Olúwa fa ilé onígbèéraga ya lulẹ̀, 26Olúwa kórìíra èrò ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n mímọ́ ni ọ̀rọ̀ ẹni pípé. 27Ọ̀kánjúwà ènìyàn mú ìyọnu bá ilé rẹ̀ 28Ọkàn olódodo ń wọn ìdáhùn wò 29Olúwa jìnnà sí ènìyàn búburú 30Ojú tó túká máa ń mú ayọ̀ wá fún ọkàn, 31Ẹni tí ó fetí sí ìbáwí tí ń fún ni ní ìyè, 32Ẹni tí ó kọ̀ ìbáwí kẹ́gàn ara rẹ̀, 33Ìbẹ̀rù Olúwa kọ́ ènìyàn ní ọgbọ́n,