Zsoltárok 103
1Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́. 2Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀, 3ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́ 4ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú 5ẹni tí ó fi ohun dídára tẹ́ ọ lọ́rùn 6Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fún 7Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli; 8Olúwa ni aláàánú àti olóore, 9Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo 10Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa 11Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀, 12Bí ìlà-oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn 13Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀, Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, 14nítorí tí ó mọ dídá wa, 15Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ rẹ̀ dàbí koríko, 16afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí rẹ̀, 17Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́ Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, 18sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ 19Olúwa ti pèsè ìtẹ́ rẹ̀ nínú ọ̀run, 20Yin Olúwa, ẹ̀yin angẹli rẹ̀, 21Yin Olúwa, ẹ̀yin ogun ọ̀run rẹ̀ gbogbo, 22Yin Olúwa, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ní Olúwa, ìwọ ọkàn mi.