YOR यशायाह अध्याय 19

यशायाह 19

1̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Ejibiti. Olúwa gun àwọsánmọ̀ tí ó yára lẹ́ṣin 2“Èmi yóò rú àwọn ará Ejibiti sókè sí ara wọn 3Àwọn ará Ejibiti yóò sọ ìrètí nù, 4Èmi yóò fi Ejibiti lé agbára Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 5Gbogbo omi inú odò ni yóò gbẹ, 6Adágún omi yóò sì di rírùn; 7àwọn igi ipadò Naili pẹ̀lú, 8Àwọn apẹja yóò sọkún kíkorò, 9Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ yóò kọminú 10Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ aṣọ yóò rẹ̀wẹ̀sì, 11Àwọn oníṣẹ́ Ṣoani ti di aláìgbọ́n, 12Níbo ni àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn rẹ wà báyìí? Olúwa àwọn ọmọ-ogun 13Àwọn ọmọ-aládé Ṣoani ti di aṣiwèrè, 14Olúwa ti da ẹ̀mí òòyì sínú wọn; 15Kò sí ohun tí Ejibiti le ṣe— 16Ní ọjọ́ náà ni àwọn ará Ejibiti yóò dàbí obìnrin. Wọn yóò gbọ̀n jìnnìjìnnì pẹ̀lú ẹ̀rù nítorí ọwọ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí a gbé sókè sí wọn. 17Ilẹ̀ Juda yóò sì di ẹ̀rù fún Ejibiti; gbogbo àwọn tí a bá ti dárúkọ Juda létí wọn ni yóò wárìrì, nítorí ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbèrò láti ṣe sí wọn. 18Ní ọjọ́ náà ìlú márùn-ún ní ilẹ̀ Ejibiti yóò sọ èdè àwọn ará Kenaani, wọn yóò sì búra àtìlẹ́yìn fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Ọ̀kan nínú wọn ni a ó sì máa pè ní ìlú ìparun. 19Ní ọjọ́ náà pẹpẹ kan yóò wà fún Olúwa ní àárín gbùngbùn Ejibiti, àti ọ̀wọ́n kan fún Olúwa ní etí bodè rẹ̀. 20Yóò sì jẹ́ àmì àti ẹ̀rí sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ilẹ̀ Ejibiti. Nígbà tí wọ́n bá ké pe Olúwa nítorí àwọn aninilára wọn, yóò rán olùgbàlà àti olùgbèjà kan sí wọn tí yóò sì gbà wọ́n sílẹ̀. 21Báyìí ni Olúwa yóò sọ ara rẹ̀ di mí mọ̀ fún àwọn ará Ejibiti àti ní ọjọ́ náà ni wọn yóò gba Olúwa gbọ́. Wọn yóò sìn ín pẹ̀lú ẹbọ ọrẹ ìyẹ̀fun, wọn yóò jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa wọn yóò sì mú un ṣẹ. 22Olúwa yóò fi àjàkálẹ̀-ààrùn kan bá Ejibiti jà; yóò bá wọn jà yóò sì tún wò wọ́n sàn. Wọn yóò yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn yóò sì wò wọ́n sàn. 23Ní ọjọ́ náà òpópónà kan yóò wá láti Ejibiti lọ sí Asiria. Àwọn ará Asiria yóò lọ sí Ejibiti àti àwọn ará Ejibiti lọ sí Asiria. Àwọn ará Ejibiti àti ará Asiria yóò jọ́sìn papọ̀. 24Ní ọjọ́ náà Israẹli yóò di ẹ̀kẹta pẹ̀lú Ejibiti àti Asiria, àní orísun ìbùkún ní ilẹ̀ ayé. 25Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò bùkún wọn yóò wí pé, “Ìbùkún ni fún Ejibiti ènìyàn mi, Asiria iṣẹ́ ọwọ́ mi, àti Israẹli ìní mi.”

दैनिक सीमा तक पहुंच गई

उच्च दैनिक सीमा के साथ AI सुविधाओं का उपयोग जारी रखने के लिए अपनी योजना को अपग्रेड करें।

सभी योजनाओं की तुलना करें →