Izaija 22
1Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó jẹ mọ́ àfonífojì ìran. 2Ìwọ ìlú tí ó kún fún rúkèrúdò, 3Gbogbo àwọn olórí i yín ti jùmọ̀ sálọ; 4Nítorí náà ni mo wí pé, “Yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi: 5Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan 6Elamu mú apó-ọfà lọ́wọ́, 7Àyànfẹ́ àfonífojì rẹ kún fún kẹ̀kẹ́ ogun, 8Gbogbo ààbò Juda ni a ti ká kúrò. 9Ìwọ rí i pé ìlú u Dafidi 10Ìwọ ka àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu 11Ìwọ mọ agbemi sí àárín ògiri méjì 12Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun, 13Ṣùgbọ́n wò ó, ayọ̀ àti ayẹyẹ wà; 14Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ èyí di mí mọ̀ létí ì mi: “Títí di ọjọ́ ikú yín a kò ní ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yìí,” ni Olúwa wí, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun. 15Èyí ni ohun tí Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, 16Kí ni ohun tí ò ń ṣe níhìn-ín yìí àti pé 17“Kíyèsára, Olúwa fẹ́ gbá ọ mú gírígírí 18Òun yóò ká ọ rúgúdù bí i òkìtì 19Èmi yóò yọ ọ́ kúrò ní ipò rẹ, 20“Ní ọjọ́ náà. Èmi yóò ké sí ọmọ ọ̀dọ̀ mi, Eliakimu ọmọ Hilkiah. 21Èmi yóò fi aṣọ rẹ wọ̀ ọ́, n ó sì so ẹ̀wọ̀n rẹ mọ́ ọn ní ọrùn, èmi ó sì gbé àṣẹ rẹ lé e lọ́wọ́. Òun yó sì jẹ́ baba fún gbogbo olùgbé e Jerusalẹmu àti fún ilé e Juda. 22Èmi yóò sì fi kọ́kọ́rọ́ ilé e Dafidi lé e ní èjìká; ohunkóhun tí ó bá ṣí, ẹnikẹ́ni kì yóò lè ti, ohunkóhun tí ó bá sì tì, ẹnikẹ́ni kì yóò le è ṣí. 23Èmi yóò sì kàn mọ́lẹ̀ bí èèkàn tí ó dúró gírígírí ní ààyè e rẹ̀; òun yóò sì jẹ́ ibùjókòó ọlá fún ilé baba rẹ̀. 24Gbogbo ògo ìdílé rẹ̀ ni wọn yóò sì fi kọ ní ọrùn: ìran rẹ̀ àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀, gbogbo ohun èlò ife, títí dé orí ago ọtí. 25“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Èèkàn tí a kàn mọ́lẹ̀ gírígírí ní ààyè e rẹ̀ yóò yẹrí, yóò dẹ̀gbẹ́ yóò sì fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ àti ẹrù tí ó létéńté lórí i rẹ̀ ni a ó gé lulẹ̀.” Olúwa ni ó ti sọ ọ́.