YOR Zechariah Chương 5

Zechariah 5

YOR · So sánh · Âm thanh

1Nígbà náà ni mo yípadà, mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, ìwé kíká ti ń fò. 2Ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?” 3Ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ègún tí ó jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé, nítorí gbogbo àwọn tí ó bá jalè ni a ó ké kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀; gbogbo àwọn tí ó bá sì búra èké ni a ó ké kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀. 4Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Èmi yóò mú un jáde, Èmi yóò si wọ inú ilé olè lọ, àti inú ilé ẹni ti o bá fi orúkọ mi búra èké, yóò si wà ni àárín ilé rẹ̀, yóò si rún pẹ̀lú igi àti òkúta inú rẹ̀.’ ” 5Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ sì jáde lọ, ó sì wí fún mi pé, “Gbé ojú rẹ sókè nísinsin yìí, kí o sì wo nǹkan tí yóò jáde lọ.” 6Mo sì wí pé, “Kí ni nǹkan náà?” 7Sì kíyèsi i, a gbé tálẹ́ǹtì òjé sókè, obìnrin kan sì nìyìí tí ó jókòó sí àárín àpẹẹrẹ òsùwọ̀n. 8Ó sì wí pé, “Èyí ni ìwà búburú.” Ó sì ti sí àárín òsùwọ̀n, ó sì ju ìdérí òjé sí ẹnu rẹ̀. 9Mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, obìnrin méjì jáde wá, ẹ̀fúùfù sì wá nínú ìyẹ́ wọn; nítorí wọ́n ní ìyẹ́ bí ìyẹ́ àkọ̀, wọ́n sì gbé àpẹẹrẹ òsùwọ̀n náà dé àárín méjì ayé àti ọ̀run. 10Mo sì sọ fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Níbo ni àwọn wọ̀nyí ń gbé òsùwọ̀n náà lọ.” 11Ó si wí fún mi pé, “Sí orílẹ̀-èdè Babeli láti kọ ilé fún un. Tí ó bá ṣetán, a ó sì fi ìdí rẹ̀ mulẹ̀, a o sì fi ka orí ìpìlẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀.”

Đã đạt giới hạn hàng ngày

Nâng cấp gói của bạn để tiếp tục sử dụng các tính năng AI với giới hạn hàng ngày cao hơn.

So sánh tất cả các gói →