YOR Ezechiele Capitolo 32

Ezechiele 32

YOR · Confronta · Audio

1Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kejìlá, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 2“Ọmọ ènìyàn, ṣe ìpohùnréré ẹkún nítorí Farao ọba Ejibiti kí o sì wí fún un: 3“ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: 4Èmi yóò jù ọ́ sí orí ilẹ̀ 5Èmi yóò tan ẹran-ara rẹ ká sórí 6Ẹ̀jẹ̀ rẹ ti ń sàn ní èmi yóò sì fi rin ilẹ̀ náà 7Nígbà tí mo bá fọ́n ọ jáde, èmi yóò pa ọ̀run dé 8Gbogbo ìmọ́lẹ̀ títàn ní ojú ọ̀run Olúwa Olódùmarè wí. 9Èmi yóò da ọkàn ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn rú 10Èmi yóò mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn dẹ́rùbà ọ́, 11“ ‘Nítorí èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: 12Èmi yóò mú kí ìjọ ènìyàn rẹ kí ó 13Gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ ni èmi yóò parun 14Lẹ́yìn náà èmi yóò mú kí omi rẹ̀ tòrò Olúwa Olódùmarè wí. 15Nígbà tí mo bá sọ Ejibiti di ahoro, Olúwa.’ 16“Èyí yìí ni ẹkún tí a yóò sun fún un. Àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀-èdè yóò sun ún; nítorí Ejibiti àti gbogbo ìjọ rẹ, wọn yóò sun ún, ní Olúwa Olódùmarè wí.” 17Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mí wá: 18“Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún lórí Ejibiti kí o sì ránṣẹ́ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ àti òun àti àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀-èdè alágbára, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ìsàlẹ̀, kòtò. 19Sọ fún wọn, ‘Ǹjẹ́ ìwọ ní ojúrere jù àwọn tí o kù lọ? Lọ sí ìsàlẹ̀ kí a sì tẹ́ ọ sí àárín àwọn aláìkọlà náà.’ 20Wọn yóò ṣubú láàrín àwọn tí a fi idà pa. A fa idà yọ; jẹ́ kí a wọ́ Ejibiti kúrò pẹ̀lú gbogbo ìjọ rẹ̀. 21Láti inú isà òkú alágbára tí í ṣe aṣáájú yóò sọ nípa Ejibiti àti àwọn àlejò rẹ̀, ‘Wọn ti wá sí ìsàlẹ̀, wọn sì sùn pẹ̀lú aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa.’ 22“Asiria wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo jagunjagun rẹ̀; àwọn isà òkú àwọn tí a ti pa sì yí i ká, gbogbo àwọn tí ó ti ipa idà ṣubú. 23Isà òkú wọn wà ní ibi tí ó jinlẹ̀ gan an nínú kòtò. Gbogbo àwọn tí ó ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè ní a pa, tí ó ti ipa idà ṣubú. 24“Elamu wà níbẹ̀, o yí isà òkú rẹ̀ ká pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀. Gbogbo wọn ni a pa, àwọn tí ó ti ipa idà ṣubú. Gbogbo àwọn tí ó ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè lọ sí ìsàlẹ̀ láìkọlà sí abẹ́ ilẹ̀. Wọ́n gba ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò. 25A ṣe ibùsùn fún un láàrín àwọn tí a pa, pẹ̀lú gbogbo ìjọ rẹ̀ tí ó yí isà òkú ká. Gbogbo wọn jẹ́ aláìkọlà, tí a fi idà pa. Nítorí pé a tan ẹ̀rù wọn ká ilẹ̀ alààyè, wọn ru ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò; a tẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn tí a pa. 26“Meṣeki àti Tubali wà níbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ogun wọn yí isà òkú wọn ká. Gbogbo wọn jẹ́ aláìkọlà, wọ́n fi idà pa wọ́n nítorí ẹ̀rù tiwọn tàn ká ilẹ̀ alààyè. 27Wọn kì yóò sì dùbúlẹ̀ ti àwọn tí ó ṣubú nínú àwọn aláìkọlà, tí wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí ipò òkú pẹ̀lú ìhámọ́ra ogun wọn, wọ́n tí fi idà wọn rọ orí wọn. Ṣùgbọ́n àìṣedéédéé wọn yóò wà ní orí egungun wọn—bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ ẹ̀rù àwọn alágbára ní ilẹ̀ alààyè. 28“Ìwọ náà, Farao, ní yóò ṣẹ, ti yóò dùbúlẹ̀ láàrín aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa. 29“Edomu wà níbẹ̀, àwọn ọba rẹ̀ àti gbogbo ọmọbìnrin ọba; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní agbára, a tẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa. Wọn dùbúlẹ̀ pẹ̀lú aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn ti o lọ sínú kòtò. 30“Gbogbo àwọn ọmọ-aládé ilẹ̀ àríwá àti gbogbo àwọn ará Sidoni wà níbẹ̀; wọn lọ sí ìsàlẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí a pa ní ìtìjú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ṣe okùnfà ẹ̀rù pẹ̀lú agbára wọn. Wọn sùn ní àìkọlà pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa, wọn sì ru ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò. 31“Farao, òun àti gbogbo jagunjagun rẹ̀ yóò rí wọn, a yóò sì tù ú nínú nítorí gbogbo ogun rẹ̀ tí a fi idà pa, ní Olúwa Olódùmarè wí. 32Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè, Farao àti gbogbo ogun rẹ̀ ni a yóò tẹ́ sí àárín aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa ní Olúwa Olódùmarè wí.”

Limite Giornaliero Raggiunto

Aggiorna il tuo piano per continuare a utilizzare le funzioni AI con limiti giornalieri più elevati.

Confronta tutti i piani →