YOR 1. Ljetopisa Poglavlje 24

1. Ljetopisa 24

YOR · Usporedi · Zvuk

1Àwọn wọ̀nyí sì ni pínpín àwọn ọmọ Aaroni. 2Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú kí ó tó di wí pé baba wọn kú, wọn kò sì ní àwọn ọmọ; bẹ́ẹ̀ ni Eleasari àti Itamari sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. 3Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Sadoku ọmọ Eleasari àti Ahimeleki ọmọ Itamari, Dafidi sì yà wọ́n nípa nínú ìpín fún ìyàsọ́tọ̀ àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn. 4A rí ọ̀pọ̀ àwọn olórí lára àwọn ọmọ Eleasari ju lára àwọn ọmọ Itamari lọ, wọ́n sì pín wọn lẹ́sẹ lẹ́sẹ: mẹ́rìndínlógún olórí láti ìdílé ọmọ Eleasari ìran wọn àti olórí méjọ ìdílé láti ara àwọn ọmọ Itamari. 5Wọ́n sì pín wọn láìṣègbè nípa yíya ìpín, nítorí àwọn olórí ibi mímọ́ àti àwọn olórí ilé Ọlọ́run wà láàrín àwọn ọmọ méjèèjì Eleasari àti Itamari. 6Ṣemaiah ọmọ Netaneli, akọ̀wé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Lefi sì kọ orúkọ wọn níwájú ọba àti àwọn ìjòyè: Sadoku àlùfáà, Ahimeleki ọmọ Abiatari àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà tí a mú láti ọ̀dọ̀ Eleasari àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ Itamari. 7Ìpín èkínní jáde sí Jehoiaribu, 8ẹlẹ́ẹ̀kẹta sì ni Harimu, 9ẹ̀karùnún sì ni Malkiah, 10èkeje sì ni Hakosi, 11ẹ̀kẹsànán sì ni Jeṣua, 12ẹ̀kọkànlá sì ni Eliaṣibu, 13ẹ̀kẹtàlá sì ni Hupa, 14ẹ̀kẹdógún sì ni Bilgah, 15ẹ̀kẹtàdínlógún sì ni Hesiri, 16ẹ̀kọkàndínlógún sì ni Petahiah, 17ẹ̀kọkànlélógún sì ni Jakini, 18ẹ̀kẹtàlélógún sì ni Delaiah, 19Àwọn wọ̀nyí ni a yàn fún iṣẹ́ ìsìn nígbà tí wọ́n wọ ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìlànà àti àṣẹ tí a ti fi fún wọn láti ọwọ́ baba ńlá wọn Aaroni gẹ́gẹ́ bí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tí pàṣẹ fun un. 20Ìyókù àwọn ọmọ Lefi. 21Àti gẹ́gẹ́ bí Rehabiah, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Rehabiah, Iṣiah sì ni alákọ́kọ́. 22Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Isari: Ṣelomiti; 23Àwọn ọmọ Hebroni: 24Àwọn ọmọ Usieli: Mika; 25Àwọn arákùnrin Mika: Iṣi; 26Àwọn ọmọ Merari: Mahili àti Muṣi. 27Àwọn ọmọ Merari. 28Láti Mahili: Eleasari, ẹni tí kò ni àwọn ọmọ. 29Láti Kiṣi. Àwọn ọmọ Kiṣi: Jerahmeeli. 30Àti àwọn ọmọ Muṣi: Mahili, Ederi àti Jerimoti. 31Wọ́n sì ṣé kèké gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin wọn àwọn ọmọ Aaroni ṣe ṣẹ́, níwájú ọba Dafidi àti Sadoku, Ahimeleki, àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi. Àwọn ìdílé àgbàgbà arákùnrin wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ lórí àwọn arákùnrin wọn kéékèèké.

Dnevna Ograničenja Dosegnuta

Nadogradi svoj plan kako bi nastavio/nastavila koristiti AI značajke s većim dnevnim ograničenjima.

Usporedi sve planove →