YOR Leviticus Chương 3

Leviticus 3

YOR · So sánh · Âm thanh

1 ‘Bí ọrẹ ẹnìkan bá jẹ́ ọrẹ àlàáfíà, tí ó sì mú ẹran wá láti inú agbo màlúù yálà akọ tàbí abo, kí ó mú èyí tí kò ní àbùkù wá síwájú Olúwa. 2Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká. 3Láti ara ọrẹ àlàáfíà ni kí ẹni náà ti mú ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa, gbogbo ọ̀nà tí ó bo nǹkan inú ẹran náà àti gbogbo ọ̀rá tí ó so mọ́ wọn. 4Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá ara rẹ̀ tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀, àti gbogbo ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín. 5Nígbà náà ni àwọn ọmọ Aaroni yóò sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun tí a fi iná sun, àní òórùn dídùn sí Olúwa. 6“ ‘Bí ó bá ṣe inú agbo ewúrẹ́ àti àgùntàn ni ó ti mú ọrẹ àlàáfíà wá fún Olúwa kí ó mú akọ tàbí abo tí kò ní àbùkù. 7Bí ó bá ṣe pé ọ̀dọ́-àgùntàn ni ó mú, kí ó mú un wá síwájú Olúwa. 8Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á níwájú àgọ́ ìpàdé, kí àwọn ọmọ Aaroni wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká. 9Kí o sì mú wá nínú ẹbọ àlàáfíà náà, fún ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa; ọ̀rá rẹ̀ àti gbogbo ìrù rẹ̀ tí ó ní ọ̀rá, òun ni kí o mú kúrò súnmọ́ egungun ẹ̀yìn àti ọ̀rá tí ó bo ìfun lórí; àti gbogbo ọ̀rá tí ń bẹ lára ìfun. 10Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀ àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí o yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín. 11Kí àlùfáà sun ún lórí pẹpẹ bí oúnjẹ ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa. 12“ ‘Bí ó bá ṣe pé ewúrẹ́ ni ó mú, kí ó mú un wá síwájú Olúwa. 13Kí ó gbé ọwọ́ lé e lórí. Kí ó sì pa á ní iwájú àgọ́ ìpàdé. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Aaroni yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká. 14Lára ọrẹ tó mú wá, kí ó mú ẹbọ sísun fún Olúwa, gbogbo ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú rẹ̀ àti ohun gbogbo tó so mọ́ ọn. 15Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá ara rẹ̀ tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀ àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín. 16Kí àlùfáà sun ún lórí pẹpẹ bí oúnjẹ, ọrẹ tí a fi iná sun, ní òórùn dídùn. Gbogbo ọ̀rá rẹ̀ jẹ́ ti Olúwa. 17“ ‘Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún àwọn ìran tó ń bọ̀, ní gbogbo ibi tí ẹ bá ń gbé, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ọ̀rá tàbí ẹ̀jẹ̀.’ ”

Đã đạt giới hạn hàng ngày

Nâng cấp gói của bạn để tiếp tục sử dụng các tính năng AI với giới hạn hàng ngày cao hơn.

So sánh tất cả các gói →