1 พงศ์กษัตริย์ 19
1Ahabu sì sọ gbogbo ohun tí Elijah ti ṣe fún Jesebeli àti bí ó ti fi idà pa gbogbo àwọn wòlíì. 2Nítorí náà Jesebeli rán oníṣẹ́ kan sí Elijah wí pé, “Kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí èmi kò bá ṣe ẹ̀mí rẹ bí ọ̀kan nínú wọn ní ìwòyí ọ̀la.” 3Elijah sì bẹ̀rù, ó sá fún ẹ̀mí rẹ̀. Nígbà tí ó sì dé Beerṣeba ti Juda, ó sì fi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀, 4nígbà tí òun tìkára rẹ̀ sì lọ ní ìrìn ọjọ́ kan sí aginjù, ó sì wá sí ibi igi ọwọ̀ kan, ó sì jókòó lábẹ́ rẹ̀, ó sì gbàdúrà kí òun bá le kú, wí pé, “Mo ti ní tó, Olúwa, gba ẹ̀mí mi kúrò; nítorí èmi kò sàn ju àwọn baba mi lọ.” 5Nígbà náà ni ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi, ó sì sùn lọ. 6Ó sì wò ó yíká, àkàrà tí a dín lórí ẹ̀yín iná, àti orù-omi wà lẹ́bàá orí rẹ̀. Ó sì jẹ, ó sì mu, ó sì tún dùbúlẹ̀. 7Angẹli Olúwa sì tún padà wá lẹ́ẹ̀kejì, ó sì tún fi ọwọ́ tọ́ ọ, ó sì wí pé, “Dìde, kí ó jẹun, nítorí ìrìnàjò náà jì fún ọ.” 8Ó si dìde, ó sì jẹ, ó mu, o sì fi agbára oúnjẹ yìí lọ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru sí Horebu, òkè Ọlọ́run. 9Níbẹ̀, ó lọ sí ibi ihò òkúta, ó sì wọ̀ níbẹ̀. Olúwa farahan Elijah Olúwa sì tọ Elijah wá wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín yìí, Elijah?” 10Ó sì dáhùn wí pé, “Èmi ti ń jowú fún Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. Àwọn ọmọ Israẹli ti kọ májẹ̀mú rẹ sílẹ̀, wọ́n sì ti wó àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń wá ẹ̀mí mi láti gbà á kúrò báyìí.” 11Olúwa sì wí pé, “Jáde lọ, kí o sì dúró lórí òkè níwájú Olúwa, nítorí Olúwa fẹ́ rékọjá.” Olúwa; ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínú ìjì náà. Lẹ́yìn ìjì náà ni ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀, ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínú ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀ náà. 12Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀ náà ni iná wá, ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínú iná náà. Àti lẹ́yìn iná náà ni ohùn kẹ́lẹ́ kékeré wá. 13Nígbà tí Elijah sì gbọ́ ọ, ó sì fi agbádá rẹ̀ bo ojú rẹ̀, ó sì jáde lọ, ó dúró ní ẹnu ihò òkúta náà. 14Ó sì dáhùn pé, “Èmi ti ń jowú fún Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. Àwọn ọmọ Israẹli ti kọ májẹ̀mú rẹ sílẹ̀, wọ́n sì ti wó pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń gbìyànjú láti pa èmi náà báyìí.” 15Olúwa sì wí fún un pé, “Padà lọ sí ọ̀nà tí ìwọ ti wá, kí o sì lọ sí aginjù Damasku. Nígbà tí ìwọ bá dé ibẹ̀, fi òróró yan Hasaeli ní ọba lórí Aramu. 16Tún fi òróró yan Jehu ọmọ Nimṣi ní ọba lórí Israẹli, àti kí o fi òróró yan Eliṣa ọmọ Ṣafati, ará Abeli-Mehola ní wòlíì ní ipò rẹ. 17Jehu yóò pa ẹni tí ó bá sálà kúrò lọ́wọ́ idà Hasaeli, Eliṣa yóò sì pa ẹni tí ó bá sálà kúrò lọ́wọ́ idà Jehu. 18Síbẹ̀, èmi ti pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) ènìyàn mọ́ fún ara mi ní Israẹli, àní gbogbo eékún tí kò ì tí ì kúnlẹ̀ fún òrìṣà Baali, àti gbogbo ẹnu tí kò ì tí ì fi ẹnu kò ó ní ẹnu.” 19Bẹ́ẹ̀ ni Elijah lọ kúrò níbẹ̀, ó sì rí Eliṣa ọmọ Ṣafati. Ó ń fi àjàgà màlúù méjìlá tulẹ̀ níwájú rẹ̀, àti òun náà níwájú èkejìlá. Elijah sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì da agbádá rẹ̀ bò ó. 20Nígbà náà ni Eliṣa sì fi àwọn màlúù sílẹ̀, ó sì sáré tọ Elijah lẹ́yìn. Ó wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí èmi lọ fi ẹnu ko baba àti ìyá mi ní ẹnu. Nígbà náà ni èmi yóò tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.” 21Eliṣa sì fi í sílẹ̀, ó padà sẹ́yìn. Ó sì mú àjàgà màlúù rẹ, ó sì pa wọ́n. Ó sì fi ohun èlò àwọn màlúù náà bọ́ ẹran wọn, ó sì fi fún àwọn ènìyàn, wọ́n sì jẹ. Nígbà náà ni ó sì dìde láti tọ Elijah lẹ́yìn, ó sì ṣe ìránṣẹ́ fún un.