YOR 1 Chronicles Sura 16

1 Chronicles 16

YOR · Linganisha · Sauti

1Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, wá sínú àgọ́ ti Dafidi ti pèsè fún un, wọ́n sì gbé ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀ kalẹ̀ níwájú Ọlọ́run. 2Lẹ́yìn tí Dafidi parí ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, ó bùkún àwọn ènìyàn ní orúkọ Olúwa. 3Nígbà náà ó fún olúkúlùkù ọkùnrin àti obìnrin ọmọ Israẹli ní ìṣù àkàrà kan, àkàrà dídùn ti àkókò kan àti àkàrà dídùn ti èso àjàrà kan. 4Ó yan díẹ̀ lára àwọn ará Lefi láti máa jọ́sìn níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa, àti láti ṣe ìrántí àti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa, Ọlọ́run Israẹli. 5Asafu ni olóyè, àtẹ̀lé rẹ ni Sekariah, Jehieli, Ṣemiramotu, Asieli, Mattitiah, Eliabu, Benaiah, Obedi-Edomu àti Jeieli, àwọn ni yóò lu ohun èlò orin olókùn àti dùùrù haapu. Asafu ni yóò lu símbálì kíkan. 6Àti Benaiah àti Jahasieli àwọn àlùfáà ni yóò fọn ìpè nígbà gbogbo níwájú àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú ti Ọlọ́run. 7Ní ọjọ́ náà Dafidi kọ́kọ́ fi lé Asafu àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ orin Dafidi ti ọpẹ́ sí Olúwa. 8Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ẹ pe orúkọ rẹ̀, 9Ẹ kọrin sí i, ẹ kọrin ìyìn, sí i, 10Ìyìn nínú orúkọ rẹ̀ mímọ́; Olúwa kí ó yọ̀. 11Ẹ wá Olúwa àti agbára rẹ̀; 12Rántí àwọn ìyanu tí Ó ti ṣe, 13A! ẹ̀yin ìran ọmọ Israẹli ìránṣẹ́ rẹ̀, 14Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa; 15Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé, 16májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu, 17Ó ṣe ìdánilójú u rẹ̀ fún Jakọbu, 18“Sí ọ, ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ Kenaani. 19Nígbà tí wọn kéré ní iye, 20wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè 21Kò gba ọkùnrin kankan láyè láti pọ́n wọn lójú; 22“Má ṣe fọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi; 23Kọrin sí Olúwa gbogbo ayé; 24Kéde ògo à rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, 25Nítorí títóbi ni Olúwa òun sì ni ìyìn yẹ jùlọ; 26Nítorí gbogbo àwọn ọlọ́run orílẹ̀-èdè jẹ́ àwọn òrìṣà, Olúwa dá àwọn ọ̀run. 27Dídán àti ọláńlá ni ó wà níwájú rẹ̀; 28Fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè, Olúwa. 29Fún Olúwa ní ìyìn nítorí orúkọ rẹ̀; Olúwa nínú inú dídùn ìwà mímọ́ rẹ̀. 30Wárìrì níwájú rẹ̀, gbogbo ayé! 31Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, jẹ́ kí ayé kí ó ṣe inú dídùn; Olúwa jẹ ọba!” 32Jẹ́ kí ọ̀run kí ó tún dún padà, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀; 33Nígbà náà ni igi igbó yóò kọrin, Olúwa, 34Fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára; 35Ké lóhùn rara, “Gbà wá, Ọlọ́run olùgbàlà a wa; 36Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, Olúwa.” 37Dafidi fi Asafu àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa láti jíṣẹ́ níbẹ̀ déédé, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe gbà. 38Ó fi Obedi-Edomu àti méjìdínláàádọ́rin ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú wọn. Obedi-Edomu mọ Jedutuni, àti Hosa pẹ̀lú jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà. 39Dafidi fi Sadoku àlùfáà àti àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níwájú Àgọ́ Olúwa ní ibi gíga ní Gibeoni. 40Láti gbé pẹpẹ ẹbọ sísun déédé, àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ sínú òfin Olúwa, tí ó ti fún Israẹli. 41Pẹ̀lú wọn ni Hemani àti Jedutuni àti ìyókù tí a mú àti yàn nípasẹ̀ orúkọ láti fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró títí láéláé 42Hemani àti Jedutuni ni wọ́n dúró fún fífọn ìpè àti Kimbali àti fún lílo ohun èlò yòókù fún orin Ọlọ́run. Àwọn ọmọ Jedutuni wà ní ipò dídúró ní ẹnu-ọ̀nà. 43Nígbà náà gbogbo àwọn ènìyàn kúrò, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀: Dafidi yípadà láti súre fún ìdílé rẹ̀.

Kikomo cha Kila Siku Kimefikia

Boresha mpango wako ili kuendelea na matumizi ya vipengele vya AI na mipango ya juu ya kila siku.

Linganisha mipango yote →