Klagovisorna 3
1Èmi ni ọkùnrin tí ó rí ìpọ́njú 2Ó ti lé mi jáde ó sì mú mi rìn 3Nítòótọ́, ó ti yí ọwọ́ rẹ̀ padà sí mi 4Ó jẹ́ kí àwọ̀ mi àti ẹran-ara mi gbó 5Ó ti fi mí sí ìgbèkùn, ó sì ti yí mi ká 6Ó mú mi gbé nínú òkùnkùn, 7Ó ti tì mí mọ́ ilé, nítorí náà n kò le è sálọ; 8Pàápàá nígbà tí mo ké fún ìrànlọ́wọ́, 9Ó fi ògiri òkúta dí ọ̀nà mi; 10Bí i beari tí ó dùbúlẹ̀, 11Ó wọ́ mi kúrò ní ọ̀nà, ó tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ 12Ó fa ọfà rẹ̀ yọ 13Ó fa ọkàn mí ya 14Mo di ẹni yẹ̀yẹ́ láàrín àwọn ènìyàn mi; 15Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkorò 16Ó ti fi òkúta kán eyín mi; 17Mo ti jìnnà sí àlàáfíà; 18Nítorí náà mo wí pé, “Ògo mi ti lọ Olúwa.” 19Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi, 20Mo ṣèrántí wọn, 21Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn 22Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé, 23Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀; 24Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa; 25Dídára ni Olúwa fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀, 26Ó dára kí a ní sùúrù Olúwa. 27Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgà 28Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, Olúwa ti fi fún un. 29Jẹ́ kí ó bo ojú rẹ̀ sínú eruku— 30Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a, 31Ènìyàn kò di ìtanù 32Lóòtítọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn, 33Nítorí kò mọ̀ ọ́n mọ̀ mú ìpọ́njú wá 34Láti tẹ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ 35Láti ṣẹ́ ọmọ ènìyàn fún ẹ̀tọ́ rẹ̀ 36láti yí ìdájọ́ ènìyàn padà, 37Ta ni yóò sọ̀rọ̀ tí yóò rí bẹ́ẹ̀ 38Ǹjẹ́ kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá-ògo jùlọ 39Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè ṣe ń kùn 40Ẹ jẹ́ kí a yẹ ọ̀nà wa, kí a sì dán an wò, Olúwa lọ. 41Ẹ jẹ́ kí a gbé ọkàn àti ọwọ́ wa sókè 42“Àwa ti ṣẹ̀ a sì ti ṣọ̀tẹ̀ 43“Ìwọ fi ìbínú bo ara rẹ ìwọ sì ń lépa wa; 44Ìwọ ti fi àwọsánmọ̀ bo ara rẹ 45Ó ti sọ wá di èérí àti ààtàn 46“Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti la ẹnu wọn 47Àwa ti jìyà àti ìparun, 48Omijé ń sàn ní ojú mi bí odò 49Ojú mi kò dá fún omijé, 50títí ìgbà tí Olúwa yóò síjú wolẹ̀ 51Ohun tí mo rí mú ìbẹ̀rù wá ọkàn mi 52Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí 53Wọ́n gbìyànjú láti mú òpin dé bá ayé mi nínú ihò 54Orí mi kún fún omi, 55Mo pe orúkọ rẹ, Olúwa, 56Ìwọ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, “Má ṣe di etí rẹ 57O wá tòsí nígbà tí mo ké pè ọ́, 58Olúwa, ìwọ gba ẹjọ́ mi rò, 59O ti rí i, Olúwa, búburú tí a ṣe sí mi. 60Ìwọ ti rí ọ̀gbun ẹ̀san wọn, 61Olúwa ìwọ ti gbọ́ ẹ̀gàn wọn 62ohun tí àwọn ọ̀tá mi ń sọ 63Wò wọ́n! Ní jíjòkòó tàbí ní dídìde, 64Olúwa san wọ́n lẹ́san ohun tí ó tọ́ sí wọn 65Fi ìbòjú bò wọ́n ní ọkàn, 66Ni wọ́n lára kí o sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìbínú, Olúwa.