Немија 7
1Lẹ́yìn ìgbà tí a tún odi mọ tán tí mo sì ri àwọn ìlẹ̀kùn sí ààyè wọn, a sì yan àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin àti àwọn Lefi. 2Mo fún Hanani arákùnrin mi pẹ̀lú Hananiah olórí ilé ìṣọ́ ní àṣẹ lórí Jerusalẹmu, nítorí tí ó jẹ́ ènìyàn olóòtítọ́, ó sì bẹ̀rù Ọlọ́run jù bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti ṣe lọ. 3Mo sọ fún wọn pé, “A kò gbọdọ̀ ṣí ìlẹ̀kùn Jerusalẹmu títí oòrùn yóò fi mú. Nígbà tí àwọn aṣọ́bodè bá sì wà lẹ́nu iṣẹ́, jẹ́ kí wọn ti ìlẹ̀kùn kí wọn sì há wọn. Bákan náà, yàn nínú àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́. Àwọn mìíràn níbi tí a pín wọn sí àti àwọn mìíràn ní tòsí ilé e wọn.” 4Ìlú náà tóbi ó sì ní ààyè, ṣùgbọ́n ènìyàn inú rẹ̀ kéré, a kò sì tí ì tún àwọn ilé inú rẹ̀ kọ́. 5Nígbà náà ni Ọlọ́run mi fi sí mi ní ọkàn láti kó àwọn ọlọ́lá, àwọn ìjòyè, àti àwọn ènìyàn jọ fún ìforúkọsílẹ̀ ní ìdílé ìdílé. Mo rí ìwé àkọsílẹ̀ ìtàn ìran àwọn tí ó kọ́ gòkè padà wá láti ìgbèkùn. Èyí ni ohun tí mo rí tí a kọ sínú ìwé náà. 6Èyí ni àwọn ènìyàn agbègbè náà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti ìgbèkùn, àwọn tí Nebukadnessari ọba Babeli ti kó ní ìgbèkùn (wọ́n padà sí Jerusalẹmu àti Juda, olúkúlùkù sí ìlú u rẹ̀. 7Wọ́n jọ rìn wá pẹ̀lú u Serubbabeli, Jeṣua, Nehemiah, Asariah, Raamiah, Nahamani, Mordekai, Bilṣani, Misperi, Bigfai, Nehumu, àti Baanah). 8àwọn ọmọ 9Ṣefatia jẹ́ òjìdínnírinwó ó lé méjìlá (372) 10Arah jẹ́ ẹgbẹ̀tàléláàádọ́ta ó lé méjì (652) 11Pahati-Moabu (láti ipasẹ̀ ọmọ Jeṣua àti Joabu) jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìnlá ó lé méjìdínlógún (2,818) 12Elamu jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀fà ó lé mẹ́rin (1,254) 13Sattu jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀rin ó lé márùn-ún (845) 14Sakkai jẹ́ òjìdínlẹ́gbẹ̀rin (760) 15Binnui jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́jọ (648) 16Bebai jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n (628) 17Asgadi jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó dín méjìdínlọ́gọ́rin (2,322) 18Adonikami jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méje (667) 19Bigfai jẹ́ ẹgbàá ó lé mẹ́tàdínláàádọ́rin (2,067) 20Adini jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀ta ó lé márùn-ún (655) 21Ateri (láti ipasẹ̀ Hesekiah) jẹ́ méjìdínlọ́gọ́rùn-ún (98) 22Haṣumu jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó ó lé mẹ́jọ (328) 23Besai jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó ó lé mẹ́rin (324) 24Harifu jẹ́ méjìléláàádọ́fà (112) 25Gibeoni jẹ́ márùndínlọ́gọ́rùn (95). 26Àwọn ọmọ 27Anatoti jẹ́ méjìdínláàádóje (128) 28Beti-Asmafeti jẹ́ méjìlélógójì (42) 29Kiriati-Jearimu, Kefira, àti Beeroti jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́ta (743) 30Rama àti Geba jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé mọ́kànlélógún (621) 31Mikmasi jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà (122) 32Beteli àti Ai jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́fà (123) 33Nebo mìíràn jẹ́ méjìléláàádọ́ta (52) 34Elamu mìíràn jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́rìnléláàádọ́ta (1,254) 35Harimu jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó (320) 36Jeriko jẹ́ ọ̀tàdínnírinwó ó lé márùn-ún (345). 37Lodi, Hadidi, àti Ono jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rin ó lé ọ̀kan (721) 38Senaa jẹ́ ẹgbàajì ó dín àádọ́rin (3,930). 39Àwọn àlùfáà: 40Immeri jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀rún ó lé méjì (1,052) 41Paṣuri jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́tàdínláàádọ́ta (1,247) 42Harimu jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé mẹ́tàdínlógún (1,017). 43Àwọn ọmọ Lefi: 44Àwọn akọrin: 45Àwọn aṣọ́nà: 46Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili. 47Kerosi, Sia, Padoni, 48Lebana, Hagaba, Ṣalmai, 49Hanani, Giddeli, Gahari, 50Reaiah, Resini, Nekoda, 51Gassamu, Ussa, Pasea, 52Besai, Mehuni, Nefisimu, 53Bakbu, Hakufa, Harhuri, 54Basluti, Mehida, Harṣa, 55Barkosi, Sisera, Tema, 56Nesia, àti Hatifa. 57Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni: 58Jaala, Darkoni, Giddeli, 59Ṣefatia, Hattili, 60Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irinwó ó dín mẹ́jọ (392). 61Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti Teli-Mela, Teli-Harṣa, Kerubu, Addoni àti Immeri, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà Israẹli. 62Àwọn ọmọ 63Lára àwọn àlùfáà ni: 64Àwọn wọ̀nyí wá àkọsílẹ̀ orúkọ ìran wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí í níbẹ̀, fún ìdí èyí, a yọ wọ́n kúrò nínú àwọn tí ń ṣiṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ́. 65Baálẹ̀ sọ fún wọn nítorí náà pé wọn kò gbọdọ̀ kópa nínú jíjẹ oúnjẹ mímọ́ títí tí àlùfáà tí yóò wá tí ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Urimu àti Tumimu yóò fi dé. 66Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé òjìdínnírinwó (42,360), 67yàtọ̀ sí àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀ta dín lẹ́gbàárin ó dín ẹ̀tàlélọ́gọ́ta (7,337); wọ́n sì tún ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ òjìlúgba ó lé márùn-ún (245). 68Ẹṣin wọn jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin (736), ìbákasẹ wọn jẹ́ òjìlúgba ó dín márùn-ún (245); 69ìbákasẹ wọn jẹ́ òjìlénírinwó ó dín márùn-ún (435); kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlélọ́gbọ̀n ó dín ọgọ́rin (6,720). 70Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé náà kópa nínú ṣíṣe iṣẹ́ náà. Baálẹ̀ fún ilé ìṣúra ní ẹgbẹ̀rún (1,000) dariki wúrà, àádọ́ta àwo koto àti ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀ta lé mẹ́wàá (530) ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà. 71Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé fún ilé ìṣúra ní ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) dariki wúrà àti ẹgbọ̀kànlá (2,200) mina fàdákà. 72Àròpọ̀ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn tókù fi sílẹ̀ jẹ́ ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) dariki wúrà, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) mina fàdákà àti ẹẹ́tàdínláàdọ́rin ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà. 73Àwọn àlùfáà, àwọn Lefi, àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin, àwọn ènìyàn díẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ ilé Ọlọ́run, àti gbogbo ènìyàn Israẹli wà ní ìlú wọn.