Језекиљ 28
1Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 2“Ọmọ ènìyàn, sọ fún ọmọ-aládé Tire pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: 3Ìwọ gbọ́n ju Daniẹli lọ bí? 4Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ, 5Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹ, 6“ ‘Nítorí náà èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: 7Èmi yóò mú kí àwọn àjèjì dìde sí ọ, 8Wọn yóò mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá sínú ihò, 9Ṣé ìwọ yóò wá wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run,” 10Ìwọ yóò kú ikú aláìkọlà, Olúwa Olódùmarè wí.’ ” 11Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 12“Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún sórí ọba Tire kí ó sì sọ fún un pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: 13Ìwọ ti wà ní Edeni, ọgbà Ọlọ́run; 14A fi àmì òróró yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú kérúbù, 15Ìwọ pé ní ọ̀nà rẹ, 16Nípa ìtànkálẹ̀ òwò rẹ, 17Ọkàn rẹ gbéraga, 18Nípa ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ rẹ àti òwò àìṣòótọ́ rẹ, 19Gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó mọ̀ ọ́n, 20Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 21“Ọmọ ènìyàn, kọ ojú sí Sidoni; kí o sì sọtẹ́lẹ̀ sí i, 22kí ó sì wí pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Olúwa, 23Èmi yóò sì rán àjàkálẹ̀-ààrùn sínú rẹ, Olúwa. 24“ ‘Kì yóò sì ṣí ẹ̀gún tí ń gun ni ní ilẹ̀ Israẹli mọ́, tàbí ẹ̀gún bíbani nínú jẹ́ ti gbogbo àwọn tí wọn wà ní àyíká wọn, tí wọ́n sì ń fi ojú yẹpẹrẹ wò wọ́n, nígbà náà ni wọn yóò mọ́ wí pé èmi ni Olúwa Olódùmarè. 25“ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí èmi yóò bá sa àwọn ènìyàn Israẹli jọ kúrò ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fọ́nká sí, tí a ó sì yà mí sí mímọ́ láàrín wọn lójú àwọn aláìkọlà. Nígbà náà ni wọn yóò gbé ní ilẹ̀ àwọn tìkálára wọn, èyí tí mo fún ìránṣẹ́ mi Jakọbu. 26Wọn yóò sì máa gbé ní inú rẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì kọ́lé, wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà; nítòótọ́ wọn yóò wà ní ìbàlẹ̀ àyà, nígbà tí èmi bá ti mú ìdájọ́ mi ṣẹ̀ sí ara àwọn tí ń ṣátá wọn ní gbogbo àyíká wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.’ ”