Esdras 2
1Lákòókò náà, wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn agbègbè Juda tí ó gòkè wá láti ìgbèkùn láàrín àwọn tí a kó lọ, ẹni tí Nebukadnessari ọba Babeli ti fi agbára mú ní ìgbèkùn lọ sí Babeli (wọ́n padà sí Jerusalẹmu àti Juda, olúkúlùkù sí ìlú rẹ̀. 2Àwọn wọ̀nyí bá Serubbabeli, Jeṣua, Nehemiah, Seraiah, Reelaiah, Mordekai, Bilṣani, Mispari, Bigfai, Rehumu àti Baanah wá). 3Àwọn ọmọ 4Ṣefatia jẹ́ òjìdínnírinwó ó lé méjìlá (372) 5Arah jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (775) 6Pahati-Moabu (láti ipasẹ̀ àwọn ọmọ Jeṣua àti Joabu) jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹgbẹ̀rin lé méjìlá (2,812) 7Elamu jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀fà ó lé mẹ́rin (1,254) 8Sattu jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rún ó lé márùn-ún (945) 9Sakkai jẹ́ òjìdínlẹ́gbẹ̀rin (760) 10Bani jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì (642) 11Bebai jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé mẹ́tàlélógún (623) 12Asgadi jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé méjìlélógún (1,222) 13Adonikami jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà (666) 14Bigfai jẹ́ ẹgbàá ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (2,056) 15Adini jẹ́ àádọ́ta lé ní irinwó ó lé mẹ́rin (454) 16Ateri (nípasẹ̀ Hesekiah) jẹ́ méjìdínlọ́gọ́run (98) 17Besai jẹ́ ọrùndínnírinwó ó lé mẹ́ta (323) 18Jora jẹ́ méjìléláàádọ́fà (112) 19Haṣumu jẹ́ igba ó lé mẹ́tàlélógún (223) 20Gibbari jẹ́ márùndínlọ́gọ́rùn (95). 21Àwọn ọmọ 22Netofa jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (56) 23Anatoti jẹ́ méjìdínláàádóje (128) 24Asmafeti jẹ́ méjìlélógójì (42) 25Kiriati-Jearimu, Kefira àti Beeroti jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́ta (743) 26Rama àti Geba jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé mọ́kànlélógún (621) 27Mikmasi jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà (122) 28Beteli àti Ai jẹ́ igba ó lé mẹ́tàlélógún (223) 29Nebo jẹ́ méjìléláàádọ́ta (52) 30Magbiṣi jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́jọ (156) 31Elamu mìíràn jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́rìnléláàádọ́ta (1,254) 32Harimu jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó (320). 33Lodi, Hadidi àti Ono jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rin ó lé márùn-ún (725) 34Jeriko jẹ́ ọ̀tàdínnírinwó ó lé márùn-ún (345) 35Senaa jẹ́ egbèji dín lógún ó lé ọgbọ̀n (3,630). 36Àwọn àlùfáà. 37Immeri jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀rún ó lé méjì (1,052) 38Paṣuri jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́tàdínláàádọ́ta (1,247) 39Harimu jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé mẹ́tàdínlógún (1,017). 40Àwọn ọmọ Lefi. 41Àwọn akọrin. 42Àwọn aṣọ́bodè. 43Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili. 44Kerosi, Siaha, Padoni, 45Lebana, Hagaba, Akkubu, 46Hagabu, Ṣalmai, Hanani, 47Giddeli, Gahari, Reaiah, 48Resini, Nekoda, Gassamu, 49Ussa, Pasea, Besai, 50Asna, Mehuni, Nefisimu, 51Bakbu, Hakufa, Harhuri. 52Basluti, Mehida, Harṣa, 53Barkosi, Sisera, Tema, 54Nesia àti Hatifa. 55Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni. 56Jaala, Darkoni, Giddeli, 57Ṣefatia, àwọn ọmọ Hattili, 58Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irinwó ó dín mẹ́jọ (392). 59Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti Teli-Mela, Teli-Harṣa, Kerubu, Addoni àti Immeri, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà Israẹli. 60Àwọn ọmọ 61Àti nínú àwọn ọmọ àwọn àlùfáà. 62Àwọn wọ̀nyí wá ìwé ìrántí ìdílé wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni a kò kà wọ́n kún ara àlùfáà nítorí, a kà wọ́n sí aláìmọ́. 63Baálẹ̀ pa á láṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ nínú oúnjẹ mímọ́ jùlọ títí tí àlùfáà kan yóò fi ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Urimu àti Tumimu. 64Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé òjìdínnírinwó (42,360). 65Yàtọ̀ sí ẹgbẹ̀rin dín lẹ́gbàárin ó dín mẹ́tàlélọ́gọ́ta (7,337) ìránṣẹ́ ọkùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin; wọ́n ní igba (200) akọrin ọkùnrin àti obìnrin. 66Wọ́n ní ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin ẹṣin (736); ìbáaka òjìlélúgba ó lé márùn-ún (245), 67ràkunmí jẹ́ irinwó ó lé márùndínlógójì (435) àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbẹ̀rin lé lọ́gbọ̀n ó dín ọgọ́rin (6,720). 68Ní ìgbà tí wọ́n dé ilé Olúwa ní Jerusalẹmu, díẹ̀ nínú àwọn olórí àwọn ìdílé fi ọrẹ àtinúwá sílẹ̀ fún ṣíṣe àtúnkọ́ ilé Ọlọ́run ní ààyè rẹ̀. 69Gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, wọ́n fún ilé ìṣúra fún iṣẹ́ yìí ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé lẹ́gbẹ̀rún (61,000) ìwọ̀n dariki wúrà, ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) fàdákà àti ọgọ́rùn-ún ẹ̀wù àlùfáà. 70Àwọn àlùfáà, àwọn ará Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́bodè àti àwọn ìránṣẹ́ ilé Olúwa ṣe àtìpó sínú àwọn ìlú wọn, pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn, àti ìyókù àwọn ọmọ Israẹli ṣe àtìpó sínú ìlú u wọn.