YOR Objawienia Rozdział 11

Objawienia 11

YOR · Porównaj · Audio

1A sì fi ìfèéfèé kan fún mi tí o dàbí ọ̀pá-ìwọ̀n: ẹnìkan sì wí pé, “Dìde, wọn tẹmpili Ọlọ́run, àti pẹpẹ, àti àwọn tí ń sìn nínú rẹ̀. 2Sì fi àgbàlá tí ń bẹ lóde tẹmpili sílẹ̀, má sì ṣe wọ́n ọ́n; nítorí tí a fi fún àwọn aláìkọlà: ìlú mímọ́ náà ni wọn ó sì tẹ̀ mọ́lẹ̀ ní oṣù méjìlélógójì (42). 3Èmi ó sì yọ̀ǹda fún àwọn ẹlẹ́rìí mi méjèèje, wọn ó sì sọtẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ̀fà ọjọ́ ó lé ọgọ́ta (1,260) nínú aṣọ ọ̀fọ̀.” 4Wọ̀nyí ni igi olifi méjì náà, àti ọ̀pá fìtílà méjì náà tí ń dúró níwájú Olúwa ayé. 5Bí ẹnikẹ́ni bá sì fẹ́ pa wọn lára, iná ó ti ẹnu wọn jáde, a sì pa àwọn ọ̀tá wọn run, báyìí ni a ó sì pa ẹnikẹ́ni tí ó ba ń fẹ́ pa wọn lára run. 6Àwọn wọ̀nyí ni ó ni agbára láti sé ọ̀run, tí òjò kò fi lè rọ̀ ni ọjọ́ àsọtẹ́lẹ̀ wọn. Wọ́n sì ní agbára lórí omi láti sọ wọn di ẹ̀jẹ̀, àti láti fi onírúurú àjàkálẹ̀-ààrùn kọlu ayé, nígbàkígbà tí wọ́n bá fẹ́. 7Nígbà tí wọn bá sì ti parí ẹ̀rí wọn, ẹranko tí o ń tí inú ọ̀gbun gòkè wá yóò bá wọn jagun, yóò sì ṣẹ́gun wọn, yóò sì pa wọ́n. 8Òkú wọn yóò sì wà ni ìgboro ìlú ńlá náà tí a ń pè ní Sodomu àti Ejibiti nípa ti ẹ̀mí, níbi tí a gbé kan Olúwa wọ́n mọ́ àgbélébùú. 9Fún ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ ni àwọn ènìyàn nínú ènìyàn gbogbo àti ẹ̀yà, àti èdè, àti orílẹ̀, wo òkú wọn, wọn kò si jẹ kì a gbé òkú wọn sínú ibojì. 10Àti àwọn tí o ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì yọ̀ lé wọn lórí, wọn yóò sì ṣe àríyá, wọn ó sì ta ara wọn lọ́rẹ; nítorí tí àwọn wòlíì méjèèjì yìí dá àwọn tí o ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé lóró. 11Àti lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ náà, ẹ̀mí ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá wọ inú wọn, wọn sì dìde dúró ni ẹsẹ̀ wọn; ẹ̀rù ńlá sì ba àwọn tí o rí wọn. 12Wọn sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti ọ̀run wá ń wí fún wọn pé, “Ẹ gòkè wá ìhín!” Wọn sì gòkè lọ sí ọ̀run nínú ìkùùkuu àwọsánmọ̀; lójú àwọn ọ̀tá wọn. 13Ní wákàtí náà omìmì-ilẹ̀ ńlá kan sì mì, ìdámẹ́wàá ìlú náà sì wó, àti nínú omìmì-ilẹ̀ náà ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) ènìyàn ní a pa; ẹ̀rù sì ba àwọn ìyókù, wọn sì fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run. 14Ègbé kejì kọjá; sì kíyèsi i, ègbé kẹta sì ń bọ̀ wá kánkán. 15Angẹli keje sì fọn ìpè; a sì gbọ́ ohùn ńlá láti ọ̀run, wí pé, 16Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà tí wọn jókòó níwájú Ọlọ́run lórí ìtẹ́ wọn, dojúbolẹ̀, wọn sì sin Ọlọ́run, 17wí pé: 18Inú bí àwọn orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ̀ ti dé, 19A sì ṣí tẹmpili Ọlọ́run sílẹ̀ ní ọ̀run, a sì ri àpótí májẹ̀mú nínú tẹmpili rẹ̀. Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ilẹ̀ sì mi, yìnyín ńlá sì bọ́.

Osiągnięto dzienny limit

Zmień plan na nowszy, aby kontynuować korzystanie z funkcji AI z wyższymi dziennymi limitami.

Porównaj wszystkie plany →