Jeremia 20
1Ní ìgbà tí àlùfáà Paṣuri ọmọkùnrin Immeri olórí àwọn ìjòyè tẹmpili Olúwa gbọ́ tí Jeremiah ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nǹkan wọ̀nyí. 2Ó mú kí wọ́n lù wòlíì Jeremiah, kí wọ́n sì fi sínú túbú tí ó wà ní òkè ẹnu-ọ̀nà ti Benjamini ní tẹmpili Olúwa. 3Ní ọjọ́ kejì tí Paṣuri tú u sílẹ̀ nínú túbú, Jeremiah sì sọ fún un wí pé, “Orúkọ Olúwa fun ọ kì í ṣe Paṣuri bí kò ṣe ìpayà. 4Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ. Èmi yóò mú ọ di ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ sí ara rẹ àti sí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Ní ojú ara rẹ, ìwọ yóò sì rí tí wọ́n ṣubú nípa idà ọ̀tá wọn. Èmi yóò fi gbogbo àwọn ọ̀tá Juda lé ọba Babeli lọ́wọ́, òun yóò sì kó wọn lọ sí Babeli tàbí kí ó pa wọ́n. 5Èmi yóò jọ̀wọ́ gbogbo ọrọ̀ inú ìlú yìí fún ọ̀tá wọn. Gbogbo ìní wọ́n gbogbo ọlá ọba Juda. Wọn yóò sì ru ìkógun lọ sí Babeli. 6Àti ìwọ Paṣuri, gbogbo ènìyàn inú ilé rẹ yóò sì lọ ṣe àtìpó ní Babeli. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí, tí wọn yóò sì sin ọ́ síbẹ̀, ìwọ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí ìwọ ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún.” 7Olúwa, o tàn mí jẹ́, 8Nígbàkígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, èmi sì kígbe síta Olúwa ti mú àbùkù 9Ṣùgbọ́n bí mo bá sọ pé, “Èmi kì yóò dárúkọ rẹ 10Mo gbọ́ sísọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, 11Ṣùgbọ́n Olúwa ń bẹ pẹ̀lú mi gẹ́gẹ́ bí akọni ẹlẹ́rù. 12Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ìwọ tí ó ń dán olódodo wò 13Kọrin sí Olúwa! Olúwa! 14Ègbé ni fún ọjọ́ tí a bí mi! 15Ègbé ni fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún baba mi, 16Kí ọkùnrin náà dàbí ìlú Olúwa gbàkóso lọ́wọ́ rẹ̀ láìkáàánú 17Nítorí kò pa mí nínú, 18Èéṣe tí mo jáde nínú ikùn,