YOR 1 Korinthiers Hoofdstuk 2

1 Korinthiers 2

YOR · Vergelijken · Audio

1Nígbà tí èmí tọ̀ yín wá, ẹ̀yin ará, kì í ṣe nípa ọ̀rọ̀ gíga àti ọgbọ́n gíga ni mo fi bá yín sọ̀rọ̀, nígbà tí èmi ń sọ̀rọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run fún un yín. 2Èmi ti pinnu láti má mọ ohunkóhun nígbà ti mo wà láàrín yín bí kò ṣe Jesu Kristi, ẹni tí a kàn mọ́ àgbélébùú. 3Èmi sì tọ̀ yín wá ni àìlera, àti ní ẹ̀rù, àti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwárìrì. 4Ìwàásù mi àti ẹ̀kọ́ mi, kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn àti ọ̀rọ̀ tí a fi ń yí ènìyàn lọ́kàn padà, bí kò ṣe nípa ìfihàn agbára Ẹ̀mí. 5Kí ìgbàgbọ́ yín kí ó má ṣe dúró lórí ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ó dúró lórí agbára Ọlọ́run. 6Ṣùgbọ́n àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n láàrín àwọn tí a pè, ṣùgbọ́n kì í ṣe ọgbọ́n ti ayé yìí tàbí ti àwọn olórí ayé yìí, èyí tí yóò di asán. 7Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n ti Ọlọ́run tó fi ara sin, ọgbọ́n tí ó ti fi ara pamọ́, èyí tí Ọlọ́run ti lànà sílẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé fún ògo wa. 8Èyí ti ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláṣẹ ayé yìí kò mọ̀. Ìbá ṣe pé wọ́n mọ̀ ọ́n, wọn kì bá tún kan Olúwa ògo mọ́ àgbélébùú. 9Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: 10Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í hàn fún wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí rẹ̀. 11Ta ni nínú ènìyàn tí ó mọ èrò ọkàn ènìyàn kan, bí kò ṣe ẹ̀mí ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀? Bákan náà, kò sí ẹni ti ó mọ àwọn èrò Ọlọ́run, bí kò ṣe Ẹ̀mí Ọlọ́run fúnra rẹ̀. 12Àwa kò gbà ẹ̀mí ti ayé yìí, bí kò ṣe Ẹ̀mí ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, kí a lè ní òye ohun tí Ọlọ́run fi fún wa lọ́fẹ̀ẹ́. 13Èyí ni àwa ń wí, kì í ṣe èyí tí a ń kọ nípa ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi ń kọ ènìyàn, èyí tí a ń fi ohun Ẹ̀mí wé ohun Ẹ̀mí. 14Ṣùgbọ́n ènìyàn nípa ti ara kò gba ohun ti Ẹ̀mí Ọlọ́run wọ̀n-ọn-nì, nítorí pé wèrè ni wọ́n jásí fún un, òun kò sì le mọ̀ wọ́n, nítorí nípa tí Ẹ̀mí ní a fi ń wádìí wọn. 15Ṣùgbọ́n ẹni tí ó wà nípa ti ẹ̀mí ń wádìí ohun gbogbo, ṣùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni tí í wádìí rẹ̀. 16“Nítorí ta ni ó mọ ọkàn Olúwa,

Dagelijks limiet bereikt

Upgrade uw plan om AI-functies met hogere dagelijkse limieten te gebruiken.

Alle abonnementen vergelijken →