YOR Psalm Kapittel 136

Psalm 136

YOR · Sammenlign · Lyd

1 fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun; 2Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run: 3Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa, 4Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá; 5Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run; 6Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi; 7Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá; 8Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán; 9Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru; 10Fún ẹni tí ó kọlu Ejibiti lára àwọn àkọ́bí wọn; 11Ó sì mú Israẹli jáde kúrò láàrín wọn; 12Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà; 13Fún ẹni tí ó pín Òkun pupa ní ìyà; 14Ó sì mú Israẹli kọjá láàrín rẹ̀ 15Ṣùgbọ́n ó bi Farao àti ogun rẹ̀ ṣubú nínú Òkun pupa; 16Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn rẹ̀ la aginjù já 17Fún ẹni tí ó kọlu àwọn ọba ńlá; 18Ó sì pa àwọn ọba olókìkí 19Sihoni, ọba àwọn ará Amori 20Àti Ogu, ọba Baṣani; 21Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní, 22Ìní fún Israẹli, ìránṣẹ́ rẹ̀, 23Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa; 24Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa; 25Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbo 26Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run;

Daglig grense nådd

Oppgrader planen din for å fortsette å bruke AI-funksjoner med høyere daglige grenser.

Sammenlign alle planer →