잠언 31
1Àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ ti Lemueli ọba, ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ìyá rẹ̀ kọ́ ọ, 2“Gbọ́ ìwọ ọmọ mi, gbọ́ ìwọ ọmọ inú mi! 3Má ṣe lo agbára rẹ lórí obìnrin, 4“Kì í ṣe fún àwọn ọba, ìwọ Lemueli, 5kí wọn má ba à mu ọtí yó kí wọn sì gbàgbé ohun tí òfin wí, 6Fi ọtí líle fún àwọn tí ń ṣègbé 7Jẹ́ kí wọn mu ọtí kí wọn sì gbàgbé òsì wọn 8“Sọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn tí kò le sọ̀rọ̀ fúnra wọn 9Sọ̀rọ̀ kí o sì ṣe ìdájọ́ àìṣègbè 10Ta ni ó le rí aya oníwà rere? 11Ọkọ rẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé púpọ̀ nínú rẹ̀ 12Ire ní ó ń ṣe fún un, kì í ṣe ibi 13Ó sa aṣọ irun àgùntàn olówùú àti ọ̀gbọ̀ 14Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò; 15Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn; 16Ó kíyèsi oko kan, ó sì rà á; 17Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tagbára tagbára 18Ó rí i pé òwò òun pé 19Ní ọwọ́ rẹ̀, ó di kẹ̀kẹ́ òwú mú 20O la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn tálákà 21Nígbà tí òjò-dídì rọ̀, kò bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀ 22Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀; 23A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibodè ìlú 24Ó ń ṣe àwọn aṣọ dáradára ó sì ń tà wọ́n 25Agbára àti ọlá ni ó wò ọ́ láṣọ 26A sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n 27Ó ń bojútó gbogbo ètò ilé rẹ̀ 28Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde wọ́n sì pè é ní alábùkún 29“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ní ń ṣe nǹkan ọlọ́lá 30Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asán Olúwa yẹ kí ó gba oríyìn. 31Sì fún un ní èrè tí ó tọ́ sí i