YOR 민수기 장 20

민수기 20

YOR · 비교 · 오디오

1Ní oṣù kìn-ín-ní, gbogbo àgbájọ ọmọ Israẹli gúnlẹ̀ sí pápá Sini, wọ́n sì dúró ní Kadeṣi. Níbẹ̀ ni Miriamu kú, wọ́n sì sin ín. 2Omi kò sí fún ìjọ ènìyàn, àwọn ènìyàn sì kó ara wọn jọ pọ̀ sí Mose àti Aaroni, 3wọ́n bá Mose jà wọ́n sì wí pé, “Ìbá kúkú sàn kí a kú nígbà tí àwọn arákùnrin ti kú níwájú Olúwa! 4Kí ni ó dé tí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn Olúwa wá sí aginjù yìí, kí àwa àti àwọn ẹran ọ̀sìn wa bá à kú síbí? 5Kí ni ó dé tí o fi mú wa gòkè kúrò ní Ejibiti wá sí ibi búburú yìí? Ibi tí kò ní oúnjẹ tàbí igi ọ̀pọ̀tọ́, èso àjàrà tàbí pomegiranate. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí omi tí a ó mu níhìn-ín!” 6Mose àti Aaroni kúrò ní ibi àpéjọ, wọ́n sì lọ dojúbolẹ̀ sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ògo Olúwa sì farahàn wọ́n. 7Olúwa sọ fún Mose pé, 8“Mú ọ̀pá, náà kí o sì pe ìjọ àwọn ènìyàn jọ, ìwọ àti Aaroni arákùnrin rẹ, kí ẹ sọ̀rọ̀ sí àpáta náà ní ojú wọn, yóò sì tú omi rẹ̀ jáde, ìwọ ó sì fún ìjọ àti ẹran wọn mu.” 9Báyìí ni Mose mú ọ̀pá láti iwájú Olúwa wá, gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún un. 10Òun àti Aaroni pe àwọn ènìyàn jọ sí ojú kan níwájú àpáta, Mose sì sọ fún wọn, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀, àwa kì yóò lè mú omi jáde láti inú àpáta yìí wá bí?” 11Nígbà náà ni Mose gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ó sì fi ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ lu àpáta lẹ́ẹ̀méjì. Omi sì tú jáde, gbogbo ìjọ ènìyàn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì mu. 12Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé, “Nítorí pé ẹ̀yin kò gbà mí gbọ́ tó láti bu ọlá fún mi níwájú àwọn ọmọ Israẹli, ìwọ kò ní kó àwọn ìjọ ènìyàn yìí dé ilẹ̀ tí mo fún wọn.” 13Èyí ni omi ti Meriba, níbi tí àwọn ọmọ Israẹli ti bá Olúwa jà àti ibi tí O ti fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni mímọ́ láàrín wọn. 14Mose sì ránṣẹ́ láti Kadeṣi sí ọba Edomu, wí pé, 15Àwọn baba ńlá wa sọ̀kalẹ̀ wá sí Ejibiti, a sì gbé ibẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn ará Ejibiti ni wá lára àti àwọn baba wa, 16ṣùgbọ́n nígbà tí a sọkún sí Olúwa, ó gbọ́ ẹkún wa, ó sì rán angẹli kan sí wa, ó sì mú wa jáde láti Ejibiti. 17Jọ̀wọ́ jẹ́ kí a gba orílẹ̀-èdè rẹ kọjá, àwa kì yóò gba inú oko tàbí ọgbà àjàrà rẹ kọjá, tàbí mu omi láti inú kànga. A ó ma kọjá ní òpópónà ọba, àwa kì yóò yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì títí àwa yóò fi kọjá ní ilẹ̀ rẹ.” 18Ṣùgbọ́n Edomu dáhùn pé, 19Àwọn ọmọ Israẹli dáhùn pé, 20Wọ́n tún dáhùn wí pé, 21Nígbà tí Edomu sì kọ̀ jálẹ̀ láti jẹ́ kí wọn kọjá ní ilẹ̀ wọn, Israẹli yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn. 22Gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sì jáde láti Kadeṣi wọ́n sì wá sí orí òkè Hori. 23Ní orí òkè Hori, ní ẹ̀gbẹ́ ààlà Edomu Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé, 24“Aaroni yóò kú. Kò ní wọ ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí ẹ̀yin méjèèjì ṣe àìgbọ́ràn sí òfin mi níbi omi Meriba. 25Mú Aaroni àti ọmọ rẹ̀ Eleasari lọ sí orí òkè Hori. 26Bọ́ aṣọ Aaroni kí o sì gbe wọ ọmọ rẹ̀ Eleasari, nítorí pé Aaroni yóò kú síbẹ̀.” 27Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ, wọ́n lọ sí orí òkè Hori ní ojú gbogbo ìjọ ènìyàn. 28Mose bọ́ aṣọ Aaroni ó sì gbe wọ ọmọ rẹ̀ Eleasari, Aaroni sì kú sí orí òkè. Nígbà náà Mose àti Eleasari sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, 29nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn sì gbọ́ pé Aaroni ti kú, gbogbo ilé Israẹli ṣe ìdárò rẹ̀ fún ọgbọ̀n ọjọ́.

일일 한도 도달

플랜을 업그레이드하여 더 높은 일일 한도로 AI 기능을 계속 사용하세요.

모든 요금제 비교 →