Hebrejima 3
1Nítorí náà ẹ̀yin ará mímọ́, alábápín ìpè ọ̀run, ẹ gba ti aposteli àti olórí àlùfáà ìjẹ́wọ́ wa rò, àní Jesu; 2ẹni tí o ṣe olóòtítọ́ si ẹni tí ó yàn án, bí Mose pẹ̀lú tí ṣe olóòtítọ́ nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo nínú ilé Ọlọ́run. 3Nítorí a ka ọkùnrin yìí ni yíyẹ sí ògo ju Mose lọ níwọ̀n bí ẹni tí ó kọ́ ilé ti lọ́lá ju ilé lọ. 4Láti ọwọ́ ènìyàn kan ni a sá à ti kọ́ olúkúlùkù ilé; ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run. 5Mose nítòótọ́ sì ṣe olóòtítọ́ nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run, bí ìránṣẹ́, fún ẹ̀rí ohun tí a ó sọ̀rọ̀ wọ́n ní ìgbà ìkẹyìn. 6Ṣùgbọ́n Kristi jẹ́ olóòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ lórí ilé Ọlọ́run; ilé ẹni tí àwa jẹ́, bí àwa bá gbẹ́kẹ̀lé e, tí a sì di ìṣògo ìrètí wa mu ṣinṣin títí dé òpin. 7Nítorí náà gẹ́gẹ́ bi Ẹ̀mí Mímọ́ tí wí: 8ẹ má ṣe sé ọkàn yín le, 9níbi tí àwọn baba yín ti dán mi wò, 10Nítorí náà a mú inú bí mi si ìran náà, 11Bí mo tí búra nínú ìbínú mi, 12Ẹ kíyèsára, ará, kí ọkàn búburú ti àìgbàgbọ́ má ṣe wà nínú ẹnikẹ́ni yín, ní lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè. 13Ṣùgbọ́n ẹ máa gba ara yín ní ìyànjú ní ojoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ń pè ní “Òní,” kí a má ba à sé ọkàn ẹnikẹ́ni nínú yín le nípa ẹ̀tàn ẹ̀ṣẹ̀. 14Nítorí àwa di alábápín pẹ̀lú Kristi, bí àwa bá di ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé wa mú ṣinṣin títí dé òpin. 15Nígbà tí a ń wí pé, 16Àwọn ta ni ó gbọ́ tí ó sì tún ṣọ̀tẹ̀? Kì í ha ṣe gbogbo àwọn tí o jáde kúrò ní Ejibiti ní abẹ́ àkóso Mose? 17Àwọn ta ni ó sì bínú sí fún ogójì ọdún? Kì í ha ṣe sí àwọn tí ó dẹ́ṣẹ̀, òkú àwọn tí ó sùn ní aginjù? 18Àwọn wo ni ó búra fún pé wọn kì yóò wọ inú ìsinmi òun, bí kò ṣe fún àwọn tí ó ṣe àìgbọ́ràn? 19Àwa sì rí i pé wọn kò lè wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbàgbọ́.