YOR गलातियों अध्याय 5

गलातियों 5

1Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin nínú òmìnira náà èyí tí Kristi fi sọ wá di òmìnira, kí ẹ má sì ṣe tún fi ọrùn bọ̀ àjàgà ẹrú mọ́. 2Kíyèsi i, èmi Paulu ni ó wí fún yín pé, bí a bá kọ yín nílà abẹ́, Kristi kì yóò lérè fún yín ní ohunkóhun. 3Mo sì tún sọ fún olúkúlùkù ènìyàn tí a kọ ní ilà pé, ó di ajigbèsè láti pa gbogbo òfin mọ́. 4A ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Kristi, ẹ̀yin tí ń fẹ́ kí a dá yín láre nípa òfin; pé ẹ ti ṣubú kúrò nínú oore-ọ̀fẹ́. 5Nítorí nípa Ẹ̀mí àwa ń fi ìgbàgbọ́ dúró de ìrètí òdodo. 6Nítorí nínú Kristi Jesu, ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà; ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ ti ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́. 7Ẹ̀yin ti ń sáré dáradára. Ta ni dí yin lọ́wọ́ láti ṣe ìgbọ́ràn sí òtítọ́? 8Ìyípadà yìí kò ti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó pè yín wá. 9Ìwúkàrà díẹ̀ ní í mú gbogbo ìyẹ̀fun wú. 10Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé sí yín nínú Olúwa pé, ẹ̀yin kì yóò ní èrò ohun mìíràn; ṣùgbọ́n ẹni tí ń yọ yín lẹ́nu yóò ru ìdájọ́ tirẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́. 11Ṣùgbọ́n, ará, bí èmi bá ń wàásù ìkọlà síbẹ̀, kín ni ìdí tí a fi ń ṣe inúnibíni sí mi síbẹ̀? Ǹjẹ́ ìkọ̀sẹ̀ àgbélébùú ti kúrò. 12Èmi ìbá fẹ́ kí àwọn tí ń yọ yín lẹ́nu tilẹ̀ gé ẹ̀yà ara wọn kan kúrò. 13Nítorí a ti pè yín sí òmìnira, ará kìkì pé kí ẹ má ṣe lo òmìnira yín bí àǹfààní sípa ti ara, ṣùgbọ́n ẹ máa fi ìfẹ́ sin ọmọnìkejì yín. 14Nítorí pé a kó gbogbo òfin já nínú èyí pé, “Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” 15Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń bu ara yín ṣán, tí ẹ sì ń jẹ ara yín run, ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe pa ara yín run. 16Ǹjẹ́ mo ní, ẹ máa rìn nípa ti Ẹ̀mí, ẹ̀yin kì yóò sì mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara ṣẹ. 17Nítorí ti ara ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lòdì sí Ẹ̀mí, àti Ẹ̀mí lòdì sí ara, àwọn wọ̀nyí sì lòdì sí ara wọn; kí ẹ má ba à lè ṣe ohun tí ẹ̀yin ń fẹ́. 18Ṣùgbọ́n bí a bá ń ti ọwọ́ Ẹ̀mí ṣamọ̀nà yín, ẹ̀yin kò sí lábẹ́ òfin. 19Ǹjẹ́ àwọn iṣẹ́ tí ara farahàn, tí í ṣe wọ̀nyí; panṣágà, àgbèrè, ìwà èérí, wọ̀bìà, 20Ìbọ̀rìṣà, oṣó, ìkórìíra, ìjà, ìlara, ìbínú, ìmọ-tara-ẹni nìkan, ìyapa, ẹ̀kọ́ òdì. 21Àrankàn, ìpànìyàn, ìmutípara, ìréde òru, àti irú ìwọ̀nyí; àwọn ohun tí mo ń wí fún yín tẹ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún yín tẹ́lẹ̀ rí pé, àwọn tí ń ṣe nǹkan báwọ̀nyí kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run. 22Ṣùgbọ́n èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwà pẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́, 23ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni níjanu, òfin kan kò lòdì sí irú wọ̀nyí, 24Àwọn tí í ṣe ti Kristi Jesu ti kan ara wọn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀. 25Bí àwa bá wà láààyè sípa ti Ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí a sì máa rìn nípa ti Ẹ̀mí. 26Ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa ṣe ògo asán, kí a má mú ọmọnìkejì wa bínú, kí a má ṣe ìlara ọmọnìkejì wa.

दैनिक सीमा तक पहुंच गई

उच्च दैनिक सीमा के साथ AI सुविधाओं का उपयोग जारी रखने के लिए अपनी योजना को अपग्रेड करें।

सभी योजनाओं की तुलना करें →