YOR Jonas Chapitre 3

Jonas 3

YOR · Comparer · Audio

1̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jona wá nígbà kejì wí pé: 2“Dìde lọ sí Ninefe, ìlú ńlá a nì, kí o sì kéde sí i, ìkéde tí mo sọ fún ọ.” 3Jona sì dìde ó lọ sí Ninefe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa. Ninefe jẹ́ ìlú títóbi gidigidi, ó tó ìrìn ọjọ́ mẹ́ta. 4Jona sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ ìlú náà lọ ní ìrìn ọjọ́ kan, ó sì ń kéde, ó sì wí pé, “Níwọ́n ogójì ọjọ́ sí i, a ó bi Ninefe wó.” 5Àwọn ènìyàn Ninefe sì gba Ọlọ́run gbọ́. Wọ́n sì kéde àwẹ̀, gbogbo wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, bẹ̀rẹ̀ láti orí ọmọdé títí dé orí àgbà wọn. 6Ọ̀rọ̀ náà sì dé ọ̀dọ̀ ọba Ninefe, ó sì dìde kúrò lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì bọ́ aṣọ ìgúnwà rẹ̀ kúrò lára rẹ̀, ó sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì jókòó nínú eérú. 7Nígbà náà ní ó kéde rẹ̀ ni Ninefe pé, 8Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn àti ẹranko da aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara, kí wọn sì kígbe kíkan sí Ọlọ́run, sì jẹ́ kí wọn yípadà, olúkúlùkù kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀ àti kúrò ní ìwà ìpa tí ó wà lọ́wọ́ wọn. 9Ta ni ó lè mọ̀ bí Ọlọ́run yóò yípadà kí ó sì ronúpìwàdà, kí ó sì yípadà kúrò ní ìbínú gbígbóná rẹ̀, kí àwa má ṣègbé?” 10Ọlọ́run sì rí ìṣe wọn pé wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀nà ibi wọn, Ọlọ́run sì ronúpìwàdà ibi tí òun ti wí pé òun yóò ṣe sí wọn, òun kò sì ṣe e mọ́.

Limite quotidienne atteinte

Mettez à jour votre plan pour continuer à utiliser les fonctionnalités de l'IA avec des limites quotidiennes plus élevées.

Comparer tous les forfaits →