YOR Joshua Kabanata 12

Joshua 12

YOR · Ihambing · Audio

1Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí àwọn ará Israẹli ṣẹ́gun, tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn ní ìlà-oòrùn Jordani, láti odò Arnoni dé òkè Hermoni, pẹ̀lú gbogbo ìhà ìlà-oòrùn aginjù: 2Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó jẹ ọba ní Heṣboni. 3Ó sì ṣe àkóso ní orí ìlà-oòrùn aginjù láti Òkun Kinnereti sí ìhà Òkun ti aginjù (ti o túmọ̀ sí Òkun Iyọ̀), sí Beti-Jeṣimoti, àti láti gúúsù lọ dé ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè Pisga. 4Àti agbègbè Ogu ọba Baṣani, ọ̀kan nínú àwọn tí ó kù nínú àwọn ará Refaimu, ẹni tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu àti Edrei. 5Ó ṣe àkóso ní orí òkè Hermoni, Saleka, Baṣani títí dé ààlà àwọn ènìyàn Geṣuri àti Maakati, àti ìdajì Gileadi dé ààlà Sihoni ọba Heṣboni. 6Mose ìránṣẹ́ Olúwa àti àwọn ọmọ Israẹli sì borí wọn. Mose ìránṣẹ́ Olúwa sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Reubeni, àwọn ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase kí ó jẹ́ ohun ìní wọn. 7Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí Joṣua àti àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ́gun ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Jordani, láti Baali-Gadi ní àfonífojì Lebanoni sí òkè Halaki, èyí tí o lọ sí ọ̀nà Seiri (Joṣua sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Israẹli ní ilẹ̀ ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn: 8ilẹ̀ òkè, ní ẹsẹ̀ òkè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn òkè aginjù, ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ní aginjù àti nì gúúsù ilẹ̀ àwọn ará: Hiti, Amori, Kenaani, Peresi, Hifi àti àwọn ará Jebusi). 9Ọba Jeriko, ọ̀kan 10ọba Jerusalẹmu, ọ̀kan 11ọba Jarmatu, ọ̀kan 12ọba Egloni, ọ̀kan 13ọba Debiri, ọ̀kan 14ọba Horma, ọ̀kan 15ọba Libina, ọ̀kan 16ọba Makkeda, ọ̀kan 17ọba Tapua, ọ̀kan 18ọba Afeki, ọ̀kan 19ọba Madoni, ọ̀kan 20ọba Ṣimroni-Meroni, ọ̀kan 21ọba Taanaki, ọ̀kan 22ọba Kedeṣi, ọ̀kan 23ọba Dori (ní Nafoti Dori), ọ̀kan 24ọba Tirsa, ọ̀kan.

Naabot na ang Pang-araw-araw na Limitasyon

I-upgrade ang iyong plan upang magpatuloy sa paggamit ng AI features na may mas mataas na daily limits.

Ikumpara ang lahat ng plano →