Sprüche 4
1Tẹ́tí, ẹ̀yin ọmọ mi, sí ẹ̀kọ́ baba; fetísílẹ̀ kí o sì ní òye sí i. 2Mo fún ọ ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, 3Nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin ní ilé baba à mí, 4Ó kọ́ mi ó sì wí pé, 5Gba ọgbọ́n, gba òye, 6Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò ọ́, 7Ọgbọ́n ni ó ga jù; nítorí náà gba ọgbọ́n. 8Gbé e ga, yóò sì gbé ọ ga 9Yóò fi òdòdó ọ̀ṣọ́ ẹwà sí orí rẹ 10Tẹ́tí, ọmọ mi, gba ohun tí mo sọ, 11Mo tọ́ ọ ṣọ́nà ní ọ̀nà ti ọgbọ́n 12Nígbà tí o rìn, ìgbésẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́ 13Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ; 14Má ṣe gbé ẹsẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburú 15Yẹra fún un, má ṣe rìn níbẹ̀; 16Nítorí wọn kò le sùn àyàfi tí wọ́n bá ṣe ibi, 17Wọ́n ń jẹ oúnjẹ ìwà búburú 18Ipa ọ̀nà olódodo dàbí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn 19ṣùgbọ́n ọ̀nà ènìyàn búburú dàbí òkùnkùn biribiri; 20Ọmọ mi, tẹ́tí sí ohun tí mo sọ; 21Má ṣe jẹ́ kí wọ́n rá mọ́ ọ lójú 22nítorí ìyè ni wọ́n jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó rí wọn 23Ju gbogbo nǹkan tókù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́, 24Mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ; 25Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo iwájú, 26Kíyèsi ìrìn ẹsẹ̀ rẹ 27Má ṣe yà sọ́tùn ún tàbí sósì;