Genesis 36
1Wọ̀nyí ni ìran Esau, ẹni tí a ń pè ní Edomu. 2Nínú àwọn ọmọbìnrin Kenaani ni Esau ti fẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀: Adah ọmọbìnrin Eloni ará Hiti àti Oholibama, ọmọbìnrin Ana, ọmọ ọmọ Sibeoni ará Hifi. 3Ó sì tún fẹ́ Basemati ọmọ Iṣmaeli arábìnrin Nebaioti. 4Adah bí Elifasi fún Esau, Basemati sì bí Reueli, 5Oholibama pẹ̀lú sì bí Jeuṣi, Jalamu, àti Kora. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Esau bí ní Kenaani. 6Esau sì mú àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ àti àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn àti gbogbo ohun ìní mìíràn tí ó ní, ni Kenaani, ó sì kó lọ sí ilẹ̀ mìíràn, jìnà sí ibi tí Jakọbu arákùnrin rẹ̀ wà. 7Ohun ìní wọn pọ̀ ju èyí tí àwọn méjèèjì lè máa gbé ní ojú kan lọ. Ilẹ̀ tí wọ́n wà kò le gba àwọn méjèèjì nítorí àwọn ohun ọ̀sìn wọn. 8Báyìí ni Esau (tí a tún mọ̀ sí Edomu) tẹ̀dó sí àwọn orílẹ̀-èdè olókè tí Seiri. 9Èyí ni ìran Esau baba àwọn ará Edomu ní àwọn orílẹ̀-èdè olókè Seiri. 10Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Esau: 11Àwọn ọmọ Elifasi ni ìwọ̀nyí: 12Elifasi ọmọ Esau sì tún ní àlè tí a ń pè ní Timna pẹ̀lú, òun ló bí Amaleki fún un. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ọmọ Adah aya Esau. 13Àwọn ọmọ Reueli: 14Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Oholibama ọmọbìnrin Ana ọmọ ọmọ Sibeoni: tí ó bí fún Esau: 15Àwọn wọ̀nyí ni olórí nínú àwọn ọmọ Esau: 16Kora, Gatamu àti Amaleki. Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Elifasi ní Edomu wá, wọ́n jẹ́ ọmọ ọmọ Adah. 17Wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Esau, ọmọ Rueli: 18Àwọn ọmọ Oholibama aya Esau: 19Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Esau (ti o túmọ̀ sí Edomu). Àwọn wọ̀nyí ni olórí wọn. 20Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Seiri ará Hori tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà: 21Diṣoni, Eseri, àti Diṣani, àwọn wọ̀nyí olórí ènìyàn Hori, àwọn ọmọ Seiri ni ilẹ̀ Edomu. 22Àwọn ọmọ Lotani: 23Àwọn ọmọ Ṣobali: 24Àwọn ọmọ Sibeoni: 25Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ana: 26Àwọn ọmọ Diṣoni ni: 27Àwọn ọmọ Eseri: 28Àwọn ọmọ Diṣani ni: 29Àwọn wọ̀nyí ni olórí ìdílé Hori: 30Diṣoni Eseri, àti Diṣani. 31Àwọn wọ̀nyí ni ọba tí ó jẹ ní Edomu kí ó tó di pé ọba kankan jẹ lórí Israẹli: 32Bela ọmọ Beori jẹ ní Edomu. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba. 33Nígbà tí Bela kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. 34Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu láti ilẹ̀ Temani sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. 35Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi ọmọ Bedadi tí ó kọlu Midiani ní ìgbẹ́ Moabu, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Afiti. 36Nígbà tí Hadadi sì kú, Samla láti Masreka, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. 37Samla sì kú, Saulu ti Rehoboti, létí odò sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. 38Nígbà tí Saulu kú, Baali-Hanani ọmọ Akbori jẹ ọba ní ipò rẹ̀. 39Nígbà tí Baali-Hanani ọmọ Akbori kú, Hadadi ni ó jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Pau, orúkọ ìyàwó sì ni Mehetabeeli ọmọbìnrin Matiredi, ọmọbìnrin Mesahabu. 40Àwọn wọ̀nyí ni orúkọ àwọn baálẹ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Esau jáde wá, ní orúkọ ìdílé wọn, bí ìpínlẹ̀ wọn ti rí: 41Baálẹ̀ Oholibama, baálẹ̀ Ela, baálẹ̀ Pinoni, 42baálẹ̀ Kenasi, baálẹ̀ Temani, baálẹ̀ Mibsari, 43Magdieli, àti Iramu.